Listen to The Horse, The Man & the Son by Ebenezer Obey

The Horse, The Man & the Son

Ebenezer Obey

Christian & Gospel

23,103 Shazams

Featured In

Lyrics

Ko s'ogbon to le da, ko si wa to le wu Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o ... (Interlude) L'ojo t'aba bi 'mo tuntun si ile aye t'onille t' alejo lo ma ki ni kuu ewu Ota omode bere lati ni bi irakoro Ka da ni l'ojeun nu, oti bere ota nini Ka da ni l'omi nu, oti bere ota nini O ti bo so owo aye ... (Interlude) T'omo naa ba ti bere si ni rin To ba l'egbe to n jo sere, l'aarin adugbo Ti obi re ba le ra keke fun, O ti bo so owo aye To ba ni ko gbe wa, ko jo fi sere To ba ni rara, oti d'ota won O ti bo so owo aye Won ani ma gbe keke e lo A'o ba e sere mo. ... (Interlude) Ti ojo ba g'ori ojo, ti omo naa ba d'agba To bere si ni re ile iwe, to f'oju si eko rẹ, to n se dede Ti wo n ba se idanwo, to ba se ipo kinii O ti di ota on'ipo k'efa, won fun l'oruko Won ni omo teacher ni ... (Interlude) A s'eyin wa a s'eyin bo, omo 'jo si bere ise Oga ile ise ni ko ma de b'ise ni agogo mejo O n se dede, o de b'ise ni akoko, kii pa t' ise je Awon ole afajo, won fun loruko Won ni omo manager ni O ti bo s'owo aye ... (Interlude) Omo to ba n sise dede, o ye ko ni asiko igbadun Igba ti o fi j'aye. To ba lo si party nibi ti won je igbadun, to ba ni ki loo mu, lo ba ni Coca-Cola, won ni jedi-jedi lo ma pa. To ba lo si party nibi ti won je igbadun, to ba ni ki loo mu, lo ba ni Coca-Cola, won ni jedi-jedi lo ma pa. ... (Interlude) To ba tun je oga oni faaji, to n j'aye dede Champagne pelu schnapps, ti o fi n yonu Heineken beer, Star lager, Top beer Becks beer pelu Guinness, gbogbo re l'oba l'ara mu Awon eda Adamo, won fun l'oruko Oti l'alakori f'owo re mu ... (Interlude) To ba tun wa lo je, agba man, to lo aso asiko To tu l'ori obinrin, won fun l'oruko Igberaga ti p'oju, ko mo ju obinrin lo, Sina l'arakori f'owo e se ... (Interlude) To ba tun je oni suru, to ka iwe to gb'oye repete To n d'ogbon jaye, ti ki s'aapon, ti ko feran obirin Awon eda Adamo, won fun l'oruko Alakori akada ni se lo n roju koikoi ... (Interlude) Omu mi ranti, itan baba kan pelu omo re ti won sin ketekete Omu mi ranti, itan baba kan pelu omo re ti won sin ketekete Eshin pelu ketekete, o da bi motor to won gun lo s'ode Eshin pelu ketekete l'aye ojo yen, o da bi motor ti won gun lo s'ode Ketekete ti d'agba, baba pelu omo e ba mura ode, won fe r'irin ajo kan Gege bi agbalagba, baba gun ketekete, omo re rin tele lo Bi won se rin s'iwaju die, won pade Adamo, eda omo araye Omo araye ni Ow! Baba agbalagba omo re n'ile, iwo n gun ketekete Baba ba bo s'ile lori ketekete, l'oba gbé omo re s'ori ketekete Won ba mu irin ajo won pon, Won lo! Won lo!! Bi won se rin s'iwaju die, won tun pade Adamo, eda omo araye Omo araye tu ni Ow! Baba omugo, o rin n'ile, omo gun ketekete Baba ba tun sure, o gb'omo s'ile, O sare gun ketekete, o tun gb'omo s ori ketekete Eni meji-reji lori ketekete Won mu irin ajo wo pon Won lo! Won lo!! Bi won se tu rin s'iwaju die, won pade Adamo, eda omo araye Omo araye tu ni Ow! Omo ati baba, alaini anu ni yin, Eyin mejeji lori ketekete, e fe pa ketekete ni? ... (Interlude) Baba ba w'oke titi, Oni ma te yin l'orun, eyin eda omo araye Baba ba gb'omo s'ile lori ketekete Ohun naa bo s'ile lori ketekete. Ketekete n lo l'ofo, baba pelu omo re won fi ese rin tele Bi won se tu rin s'iwaju die, won pade Adamo, eda omo araye Omo araye tu ni Ow! Eyin mejeji, eru aye ni yin E rin n'ile, ketekete n lo l'ofo Baba pelu omo, re gege bi mo ti wi, won bo s'ile Ketekete n lo niwaju, won fi ese rin tele Won tun rin s'iwaju die, won pade Adamo, eda omo araye Omo araye ni Ow! Eyin mejeji, eru aye ni yin E rin n'ile, ketekete n lo l'ofo Baba ba b'oju woke, o fe ranti orin Chief Commander Oni edakun e fe yi k'ogbon Ko s'ogbon to le da, ko si wa to le wu Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o Ko s'ogbon to le da, ko si wa to le wu Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o ... (Interlude) Ko s'ogbon to le da, ko si wa to le wu Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o Ko s'ogbon to le da, ko si wa to le wu Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o Ile aye fun igba die ni o, omo araye e se re o Ile aye fun igba die ni o, omo araye e se re o A fi ka w'uwa rere, rere lo pe, omo araye e se re o Ile aye fun igba die ni o, omo araye e se re o Commander Ebenezer, do your best and leave the rest . ... (Interlude) Ile aye fun igba die ni o, omo araye e se re o Ile aye fun igba die ni o, omo araye e se re o Rere lo pe, a fi ka ma w'uwa rere, omo araye e se re o Ile aye fun igba die ni o, omo araye e se re o
Lyrics powered by www.musixmatch.com
instagramSharePathic_arrow_out