Lyrics

Amona o Amona tete wa o, amona tete bo Amona tete wa o, amona tete bo (Tori pe) Aye n ba je o, amona tete bo Aye n daru o, amona tete bo Jesu Kiristi l'amona Oun lo le tun le aye wa se A n reti re o Baba, a fe r'oju re Igba ti Jesu ba de, l'aye yi to le toro o Igba ti Jesu ba de, l'aye yi to le dara Ikiri lojojumo, nise lofin gori ofin sibe sibe ara mi gbogbo, aye o fi be toro Ologun n be lode, aye n rojo kiri Oselu tun tun wo be o, igbe laraye nke oselu to koja lo, ejo laye n ro Ologun lo tun wobe o, Igbe laraye n ke Otito o nile mo, iro laraye n fe Ododo o ri bi gba o, ese ti bori aye Afi ti Jesu ba de, laye yi to le toro Afi ti Jesu ba de, laye yii to le dara Amona tete ma bo o, amona tete ma bo wa Aye n daru lo o, ese n gori ese lojojumo Aye ma dobiripo, amona tete Amona o Amona tete wa o, amona tete bo (amona o) Amona tete wa o, amona tete bo (nitori pe) Aye n ba je o, amona tete bo Aye n daru o, amona tete bo Oun tiwe mimo wi, gbogbo re lo ti n se Oro ti Jesu wa so, gbogbo re lo n f'ara han o Ta ba wonu aye, a o ri p'aye n dogbo lo Orile ede n dide sira won, ogun at'ote nsele Mo l'ogun n'ile, ogun n'ile, ogun l'oko Wahala aye yi ma poju, alagbawi tete ma bo Mo ni laye atijo, oun gbogbo n lo dede Ojo n ro lasiko re, orun n yo lasiko re Osupa n yo lasiko re o, Oye n mu lasiko re o Isu n jade lasiko re o, agbado n jade lasiko re o Mo ni la o f'orogun, oun gbogbo n lo dede Olaju olaju Olaju lo de lo b'aye je Awon to n s'olori wa, okanjua lo poju o Dugbe dugbe kan n fi loke o, aye e je a fura Eje ki a gbadura s'oluwa o, ki wahala ma se le o Dugbe dugbe kan n mi loke o, aye e je a fura Eje ki a gbadura si baba o, ki wahala ma se le o Eyin ojogbon aye, eyin ayanfe Oluwa gbogbo Eje ka parapo o, ka gbadura s'oluwa Oluwa o f'eku elese o, ironu piwada lo n toro Oluwa o f'eku elese o, ironu piwada lo n toro Ka bere fun 'dariji ese wa, alaanu l'oluwa o Amona tete ma bo o, amona tete ma bo wa Aye n baje o, ese n gori ese lojojumo Aye ma dobiripo, amona tete Amona o Amona tete wa o, amona tete bo Amona tete wa o, amona tete bo Aye n ba je o, amona tete bo Aye n daru o, amona tete bo Ara e je a ranti, Igba aye Noah o Ema je a gbagbe gbogbo wa o, iku omi to koja o Olowo aye n wi, won niro ni Noah n pa Talika so ti re o, won nibo l'ojo ti n bo wa Lalaijiyan rara, nise ni Noah tesiwaju Lalaibikita o, omo olorun o we yin wo o Pelu iranlowo Oluwa, Oko Noah pari Eranko n wole, era n wonu oko o Awon eye oju orun gbogbo, gbogbo won lo sare wole B'elede se y'obun to, sibe o raye wole Ibe la r'omo eniyan o, to n je ti won n mu B'ewure ti j'alai gboran to, kia lo sare wole Nibe la r'omo eniyan o, to n so pe'ro ni Won komo jade, won se'gbeyawo kiri Won o beru ofin Oluwa wa Oba wa, gbogbo won lo n j'aye Bo ti ri nigbaye Noah, o un be nisi yi o Bo ti ri nigbaye Noah, o un be nisi yi o Opo lo ti n so, wipe Jesu o nide mo o Amona tete ma bo o, amona tete ma bo wa Aye n baje o, ese n gori ese lojojumo Aye ma dobiripo, amona tete Amona o Amona tete wa o, amona tete bo (amona o) Amona tete wa o, amona tete bo Aye n ba je o, amona tete bo Aye n daru o, amona tete bo A n reti e Baba Eranko gbogbo wole tan, ateye oju orun Noah pelu idile re o, won n ko jije mimu Nigba tise pari tan, Noah ba wonu oko o O wonu oko lo tarara, pelu eniyan meje Eniyan meje oun, idile Noah ni gbogbo won Nigba ti won wole tan, Oba ogo t'ilekun o O ku awon alaigboran o, lati gba'dajo won Bo ti ri nigbaye noah, oun be nisi yi o Bo ti ri nigbaye noah, oun be nisi yi o Opo lo ti n so, wipe Jesu o ni de mo o Araye n pa ro, wo ni kosi Baba Baraye ba wi titi, won a so pe kosi Jesu Won ni ko s'olugbala kankan, won l'aye o ni pare Won loun ta ba je laye, oun la o mu lo s'orun Opo lo tile ni ko s'orun, won ni ta ba ku o pari o Amona tete ma bo o, amona tete ma bo wa Ko wa sile aye o, amona tete ma bo ko wa t'aye se o, amona tete ma bo Ki won le gbagbo, pe wo nikan lolugbala o Ka ye le gbagbo, pe wo l'oba to n gbani Amona tete ma bo o, amona tete ma bo wa Aye n daru o, ese n gori ese lojojumo Aye ma dobiripo, amona tete Amona o Amona tete wa o, amona tete bo Amona tete wa o, amona tete bo (Tori pe) Aye n ba je o, amona tete bo Aye n daru o, amona tete bo
Lyrics powered by www.musixmatch.com
instagramSharePathic_arrow_out